Kabi o osi Kabi o osi Arugbo ojo, ad'agba ma tepa Kabi o osi We worship you, kabi o osi We worship you, kabi o osi Arugbo ojo, ad'agba ma tepa Kabi o osi Won o mu o lo l'edi ki won fi ewe akoko le o lori n'be Ko s'awon to gbinmo po lati so pe e je a fi joba Ab'awon wo lo duro tan ni won a ma joba n'idile won gan Awon wo lo fi o je t'o fi'n j'oba kon da wa l'ohun Ta leni isaju to mu o wa s'inu orun Ta leni to fa o ni tete wonu aye pe ko wa d'aye Oya, k'enikan fi baba tabi iya re han wa o, aare Kabi o osi Arugbo ojo ad'agba ma tepa l'oruko re Kabi o osi O l'oyun ara re, obi'ra e, o s'ora e lo'ko Ipa ti o se bi l'eere, eni ti o se yi pada Ite re l'orun kii si onipo ta o le ro l'oye Arugbo ojo ni o, ad'agba ma tepa o Ehhh iwo ni ka bi o osi Riru omi okun po, nje won o ni dake to ba l'oto Iyanrin nla tun wa, to ba k'aye tan se won o ni pare Igba t'ohun gbogbo ta ko ba di wiwo pale iwo ni o ku o Arugbo ojo, onilu a lu la'torun o Ehh eh eh eh eh kabi o osi O ko d'aye eru b'aye pe kilo fe wa ninu ohun Igba to da aye tan, o m'ohungbogbo s'aye e kon ma j'oko won O ti n gbe'bikan ki o to ko orun aare nla ni o, o se tu Ailetuwo adahunro adahunso Olunkankun ni o Arugbo ojo, ad'agba ma tepa ooo Iwo ni ka bi o osi Omomo to mo'yun sinu alaboyun to f'ori f'eti f'enu si O f'imu o f'ohungbogbo sibe e, o de d'igba kan o bi Se bi bo ba pe ki mimi o ma mi, tani n jebe o Iwo ni kabi o osi Agbara re po o ju t'ara lo, iwo lo da ara Okun re po ko de le pin, oni'mi iye Iwo lo mimi'ye si amo lasan to pada wa d'eniyan Ehh eh eh eh kabi o osi Oba ti'n f'oba je, oba to le r'oba l'oye to le ni ko ma mi mo Oba ta o gbodo bi bo ba se'n sise owo re si Ojo n'ro oye n'fun be l'orun ran l'asiko re o Agbara re po o Kabi o osi Mo ni kabi o osi
Kabi o osi Kabi o osi Alagbada ina, alawotele oorun Eh eh eh kabi o osi