Kishore Kumar Hits

King Sunny Ade - Odun Titun текст песни

Исполнитель: King Sunny Ade

альбом: Check "E"


Halleluyah o, aṣọ'pẹ (Ah)
Kasi ma yọ
Halleluyah, aṣọ'pẹ
Kasi ma yọ
Ọdun to wo'le o
To ṣoju ẹmi wa
Ko ba wa layọ
Ati ṣẹgun ọta o
Toni koni ṣoju wa
Oju wa tẹlẹ gan
Ni'woyi amọdun o
Owo nini pẹlu ọmọ rere
Ile kikọ pẹlu ẹmi gigun
Alafia lo joun gbogbo lọ
Edumare ma fi kan han wa
Halleluyah, aṣọ'pẹ
Kasi ma yọ
Halleluyah, aṣọ'pẹ
Kasi ma yọ (Yes)
Ọdún to wole o
To ṣoju ẹmi wa
Ko ba wa layọ
Ati ṣẹgun ọta o
Toni koni ṣoju wa
Oju wa tẹlẹ gan
Ni'woyi amọdun o
Owo nini pẹlu ọmọ rere
Ile kikọ pẹlu ẹmi gigun
Alafia lo joun gbogbo lọ
Edumare ma fi kan han wa
Ọpẹ yẹ Eledumare ọba o
Ọpẹ lo yẹ ọ, baba mimọ
Adupẹ lọwọ rẹ o, onibu ọrẹ
Tori ọta lun'lu ibajẹ, ọba Oluwa ko ma ni jẹ ko dun
B'oba lọ ṣẹṣẹ dun, ọmọ ọta nì o ma jẹ o r'ọdun tuntun
Tori
Ọta n lémi
Wan o le bami
Wan sare titi d'ọdọ Jesu
Moní Jésù olore ọfẹ
Mo boju w'ẹyin, awọn ọta ṣubu
Wan ṣubu lulẹ, wan sun fanfan
Mo bere wo, kilo gbe wan ṣubu?
Wan ni, Ọrọ Oluwa lo sowipe
Nipa eso wan la o fi mọ wan
Ah, nipa iwa wan la o da wan lẹjọ
Ọta n lémi
Wan o le bami
Wan sare titi d'ọdọ Jesu
Moní Jésù olore ọfẹ
Mo boju w'ẹyin, awọn ọta ṣubu (Yes)
Wan ṣubu lulẹ, wan sun fanfan
Mo bere wo, kilo gbe wan ṣubu?
Wan ni, Ọrọ Oluwa lo sowipe
Nipa eso wan la o fi mọ wan
Nipa iwa wan la o da wan lẹjọ

Поcмотреть все песни артиста

Другие альбомы исполнителя

Похожие исполнители

9ice

Исполнитель

2Baba

Исполнитель