Kishore Kumar Hits

Pastor J. A. Adelakun - Amona Tete Mabo текст песни

Исполнитель: Pastor J. A. Adelakun

альбом: Amona Tete Mabo Evergreen


Amona o
Amona tete wa o, amona tete bo
Amona tete wa o, amona tete bo (Tori pe)
Aye n ba je o, amona tete bo
Aye n daru o, amona tete bo

Jesu Kiristi l'amona
Oun lo le tun le aye wa se
A n reti re o Baba, a fe r'oju re
Igba ti Jesu ba de, l'aye yi to le toro o
Igba ti Jesu ba de, l'aye yi to le dara
Ikiri lojojumo, nise lofin gori ofin
Sibe sibe ara mi gbogbo, aye o fi be toro
Ologun n be lode, aye n rojo kiri
Oselu tun tun wo be o, igbe laraye nke
Oselu to koja lo, ejo laye n ro
Ologun lo tun wobe o, Igbe laraye n ke
Otito o nile mo, iro laraye n fe
Ododo o ri bi gba o, ese ti bori aye
Afi ti Jesu ba de, laye yi to le toro
Afi ti Jesu ba de, laye yii to le dara
Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa
Aye n daru lo o, ese n gori ese lojojumo
Aye ma dobiripo, amona tete
Amona o
Amona tete wa o, amona tete bo (amona o)
Amona tete wa o, amona tete bo (nitori pe)
Aye n ba je o, amona tete bo
Aye n daru o, amona tete bo

Oun tiwe mimo wi, gbogbo re lo ti n se
Oro ti Jesu wa so, gbogbo re lo n f'ara han o
Ta ba wonu aye, a o ri p'aye n dogbo lo
Orile ede n dide sira won, ogun at'ote nsele
Mo l'ogun n'ile, ogun n'ile, ogun l'oko
Wahala aye yi ma poju, alagbawi tete ma bo
Mo ni laye atijo, oun gbogbo n lo dede
Ojo n ro lasiko re, orun n yo lasiko re
Osupa n yo lasiko re o, Oye n mu lasiko re o
Isu n jade lasiko re o, agbado n jade lasiko re o
Mo ni la o f'orogun, oun gbogbo n lo dede
Olaju olaju
Olaju lo de lo b'aye je
Awon to n s'olori wa, okanjua lo poju o
Dugbe dugbe kan n fi loke o, aye e je a fura
Eje ki a gbadura s'oluwa o, ki wahala ma se le o
Dugbe dugbe kan n mi loke o, aye e je a fura
Eje ki a gbadura si baba o, ki wahala ma se le o
Eyin ojogbon aye, eyin ayanfe Oluwa gbogbo
Eje ka parapo o, ka gbadura s'oluwa
Oluwa o f'eku elese o, ironu piwada lo n toro
Oluwa o f'eku elese o, ironu piwada lo n toro
Ka bere fun 'dariji ese wa, alaanu l'oluwa o
Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa
Aye n baje o, ese n gori ese lojojumo
Aye ma dobiripo, amona tete
Amona o
Amona tete wa o, amona tete bo
Amona tete wa o, amona tete bo
Aye n ba je o, amona tete bo
Aye n daru o, amona tete bo

Ara e je a ranti, Igba aye Noah o
Ema je a gbagbe gbogbo wa o, iku omi to koja o
Olowo aye n wi, won niro ni Noah n pa
Talika so ti re o, won nibo l'ojo ti n bo wa
Lalaijiyan rara, nise ni Noah tesiwaju
Lalaibikita o, omo olorun o we yin wo o
Pelu iranlowo Oluwa, Oko Noah pari
Eranko n wole, era n wonu oko o
Awon eye oju orun gbogbo, gbogbo won lo sare wole
B'elede se y'obun to, sibe o raye wole
Ibe la r'omo eniyan o, to n je ti won n mu
B'ewure ti j'alai gboran to, kia lo sare wole
Nibe la r'omo eniyan o, to n so pe'ro ni
Won komo jade, won se'gbeyawo kiri
Won o beru ofin Oluwa wa Oba wa, gbogbo won lo n j'aye
Bo ti ri nigbaye Noah, o un be nisi yi o
Bo ti ri nigbaye Noah, o un be nisi yi o
Opo lo ti n so, wipe Jesu o nide mo o
Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa
Aye n baje o, ese n gori ese lojojumo
Aye ma dobiripo, amona tete
Amona o
Amona tete wa o, amona tete bo (amona o)
Amona tete wa o, amona tete bo
Aye n ba je o, amona tete bo
Aye n daru o, amona tete bo

A n reti e Baba

Eranko gbogbo wole tan, ateye oju orun
Noah pelu idile re o, won n ko jije mimu
Nigba tise pari tan, Noah ba wonu oko o
O wonu oko lo tarara, pelu eniyan meje
Eniyan meje oun, idile Noah ni gbogbo won
Nigba ti won wole tan, Oba ogo t'ilekun o
O ku awon alaigboran o, lati gba'dajo won
Bo ti ri nigbaye noah, oun be nisi yi o
Bo ti ri nigbaye noah, oun be nisi yi o
Opo lo ti n so, wipe Jesu o ni de mo o
Araye n pa ro, wo ni kosi Baba
Baraye ba wi titi, won a so pe kosi Jesu
Won ni ko s'olugbala kankan, won l'aye o ni pare
Won loun ta ba je laye, oun la o mu lo s'orun
Opo lo tile ni ko s'orun, won ni ta ba ku o pari o
Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa
Ko wa sile aye o, amona tete ma bo
Ko wa t'aye se o, amona tete ma bo
Ki won le gbagbo, pe wo nikan lolugbala o
Ka ye le gbagbo, pe wo l'oba to n gbani
Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa
Aye n daru o, ese n gori ese lojojumo
Aye ma dobiripo, amona tete
Amona o
Amona tete wa o, amona tete bo
Amona tete wa o, amona tete bo (Tori pe)
Aye n ba je o, amona tete bo
Aye n daru o, amona tete bo

Поcмотреть все песни артиста

Другие альбомы исполнителя

Похожие исполнители