Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Ko Da Nkan текст песни

Исполнитель: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

альбом: Sun No Dey Sleep


Má yọ s'ílé mi mọ', kee ṣe kúrò l'áyé, ọ'rẹ' mi
Ṣebí ilé ayé ọ'hún ò da ń kán
Má rìn lọ'ọ'dẹ' mim kee ṣe jáde l'áyé, kóo mọ gbọ' o
Àní ilé ayé ọ'hún ò da nkan, ye o

Bàbá olówó àná, onílé gogoro nkọ', àwọn dà?
A wá wọn títí, a ò mà rí wọn mọ'
Ìyá wọ'kílùúmọ', akọ'mọlẹ'rú, àwọn náà ń kọ'?
Ilẹ' mù wọn, a ò mà gbọ' wọn mọ'
Má yọ s'ílé mi mọ', kee ṣe kúrò l'áyé, ọ'rẹ' mi
Ani, ilé ayé ọ'hún ò da ń kán
Má rìn lọọ 'dẹ' mi, kee ṣe jáde l'áyé, ke mọ gbọ' o
Àní, 'lé ayé ọ'hún ò da ń kán, ye o

Bọbọ' olókìkí, tí gbogbo ayé ń wá rìrì fún
Wọn bá 'lẹ' lọ, a ò mà gbọ' wọn mọ'
Arẹwà, kò-sí-rú-mi, atẹlẹ'bíẹyẹ, wọn lò'gbà
Ehn, ìgbà wá lò wọn, a ò mà gbọ' wọn mọ
Má yọ s'ílé mi mọ', kee ṣe kúrò l'áyé ọ'rẹ' mi
Ani, ilé ayé ọ'hún ò da ń kán
Má rìn lọọ'dẹ' mi, kee ṣe jáde l'áyé ko mọ gbọ' o
Moni ilé ayé ọ'hún ò da ń kán, ye o

Ẹni ayé ń fẹ', ẹni ayé ń fẹ'
Ó lè d'ọ'tá ìlú lọ'la, ẹni ayé nfẹ'

Ẹni ò r'ọ'wọ' mú, ẹni ò r'ọ'wọ' mú
Ó lè d'ọlọ'rọ' lọla, ẹni ò r'ọwọ' mú, ye o

Ẹni aiyé ń pọnlé, ẹni aiyé ń pọ'nlé
Wọn le tu'tọ' ẹ'tẹ' si, b'ọrọ' ò bá gún mọ', ye o

Má yọ s'ílé mi mọ', kee ṣe kúrò l'áyé, ọ'rẹ' mi
Ani, ilé ayé ọ'hún ò da nkan
Má rìn lọ'ọ'dẹ' mi, kee ṣe jáde l'áyé, ke mọ gbọ' o
Moni ilé ayé ọ'hún ò da ń kán, ye o

Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán
Ilé ayé òun, ò dá ń kán
Kò dá ń kán

Поcмотреть все песни артиста

Другие альбомы исполнителя

Похожие исполнители