Àdan d'oríkodò (àdan d'oríkodò) Ó mí wò 'ṣe ẹyẹ (ó mí wò 'ṣe ẹyẹ) Tẹníbẹ'gi ló jù (tẹníbẹ'gi ló jù) Ṣé b'ígi á rú 'wé (ṣèb'ígi á rú 'wé) Ẹ má rò wọn pin o Eni ò rí ṣe l'òní Kò s'ẹ'ni t'ó m'ọla o Ìgbẹ'yìn l'aláyò ń ta o Yee, kéere o, ọba ló ní a ki yín Wọn ní ẹ má ṣ'ọlẹ o, ẹ múra sí iṣẹ' ajé Yee, kéerè o, ìjòyè ṣe yín pẹ'lẹ' Wọn ní ẹ má ṣ'àfara, ẹ jẹ' a tún ilẹ yí ṣe ♪ Kéere o, kéere Ẹ bá ń ké sí wọn o (ẹ bá ń ké sí wọn o) Àwọn a fòró ìlú (àwọn a fòró ìlú) Akótilétà l'opọ (akótilétà l'opọ) Ọ'tá a ṣe bí ọrẹ (ọtá a ṣe bí ọrẹ) T'ẹ bá f'etí s'ílẹ' Sèbí irọ àtọdúnmọ'dún Òun ni wọn ń rò l'ọbẹ' Tí wọn fi nrùn wá n'ímú Yee, kéere o, àgbà ló ní a kí yín Wọn ní, "Ẹ má gbà mọ o, p'ọmọ àpà tún borí" Yee, keére o, ará ọ'run t'àjò dé Wọn ní a b'áwọn l'ọrùn, ka gb'òmìnira tòótọ' ♪ Kéere o, kéere ♪ Àdan d'oríkodò (àdan d'oríkodò) Ó mí wò 'ṣe ẹyẹ (ó mí wò 'ṣe ẹyẹ) Ọrọ yí ń dé kùn, d'áyà (ọrọ yí ń dé kùn, d'áyà) T'ó bá yá ojú á k'ojú (t'ó bá yá ojú á k'ojú) Yee, kéere o, ọba ló ní a ki yín Wọn ní e má ṣ'àníyàn, ká ṣ'ayé 're kó yẹ wá Yee, kéere o, ará ọ'run t'àjò dé Wọn ní ẹ b'ókùn l'ọ'rùn, ka d'òmìnira tòótọ' ♪ Kéere o, kéere